MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Báwo Lo Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àlàáfíà Pẹ̀lú Arákùnrin Rẹ?
Ká sọ pé ìlú Gálílì lò ń gbé nígbà ayé Jésù. O rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù kó o lè lọ ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà. Nígbà tó o débẹ̀, o rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá ṣe àjọyọ̀ láti ọ̀nà jínjìn bíi tìẹ náà ló wà níbẹ̀. O fẹ́ fún Jèhófà ní ọrẹ ẹbọ. O fa ewúrẹ́ kan lọ́wọ́, ọ̀nà há gádígádí, o sì fẹ́ kọjá láàárín àwọn èrò tó pọ̀ lọ sí tẹ́ńpìlì. Bó o ṣe dé tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ náà tún kún fọ́fọ́ fún àwọn míì tí wọ́n wá rúbọ. Níkẹyìn, ó kàn ẹ́, àlùfáà sì sọ pé kó o mú ẹwúrẹ́ ọwọ́ rẹ wá. Àmọ́ ìgbà yẹn gangan lo rántí pé arákùnrin kan sọ pé o ṣẹ òun, oò sì mọ̀ bóyá àárín èrò ni onítọ̀hún wà àbí ibòmíì láàárín ìlú. Jésù ṣàlàyé ohun tó yẹ kó o ṣe. (Ka Mátíù 5:24.) Bí Jésù ṣe sọ, báwo ni ìwọ àti arákùnrin rẹ tó sọ pé o ṣẹ òun ṣe lè wá àlàáfíà? Nínú àwọn ìdáhùn alápá-méjì tó wà nísàlẹ̀ yìí, yan èyí tó o rò pé ó yẹ kí èèyàn ṣe, kó o sì sàmì sí àpótí kékeré tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ó YẸ KÓ O . . .
-
bá a sọ̀rọ̀, kìkì tó o bá rò pé ohun tó ń tìtorí ẹ̀ bínú tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ
-
gbìyànjú láti tún ojú ìwòye arákùnrin rẹ ṣe tó o bá rò pé ó ti tètè máa ń bínú jù tàbí pé òun náà jẹ̀bi
-
fara balẹ̀ tẹ́tí sí arákùnrin rẹ bó ṣe ń ṣàlàyé ohun tó ń dùn ún fún ẹ, kódà bí ọ̀rọ̀ náà kò bá yé ẹ délẹ̀délẹ̀, bẹ̀ ẹ́ látọkànwá fún ọgbẹ́ ọkàn tí ọ̀rọ̀ náà ti fà fún un tàbí fún àwọn ohun tí ọ̀rọ̀ náà ti dá sílẹ̀
Ó YẸ KÍ ARÁKÙNRIN Ẹ . . .
-
sọ ohun tó o ṣe yìí fún àwọn ẹlòmíì nínú ìjọ, káwọn náà lè tì í lẹ́yìn
-
fìbínú sọ̀rọ̀ sí ẹ, kó tú gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà jáde, kó sì sọ pé, àfi kó o gbà pé ìwọ lo jẹ̀bi
-
gbà pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó o ní ló jẹ́ kó o wá bá òun àti pé ó gba pé kéèyàn lo ìgboyà kó tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, kó sì dárí jì ẹ́ látọkàn wá
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í fi ẹran rúbọ lóde òní nínú ìjọsìn wa, kí ni Jésù ń kọ́ wa nípa wíwá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin wa àti irú ìjọsìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?