MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
À Ń Fìfẹ́ Hàn Láwọn Àpéjọ Tá À Ń Ṣe Lọ́dọọdún
A máa ń gbádùn àwọn àpéjọ wa ọdọọdún gan-an. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, àwọn àpéjọ tá à ń ṣe lóde òní máa ń jẹ́ ká lè jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ara wa. A máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀, èyí sì ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. A tún máa ń gbádùn àkókò alárinrin pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ẹbí wa. Torí pé a mọrírì àpéjọ yìí gan-an, a máa ń ríi pé a ò pa ọjọ́ kankan jẹ.
Tá a bá wà nírú àpéjọ bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa ronú nípa bá a ṣe máa fìfẹ́ hàn sáwọn míì, kó má jẹ́ tara wa nìkan làá máa rò. (Ga 6:10; Heb 10:24, 25) Tá a bá di ilẹ̀kùn mú fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan, tó sì jẹ́ pé àyè ìjókòó tá a nílò nìkan la gbà sílẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé ire àwọn míì là ń wá. (Flp 2:3, 4) A tún máa ń ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun láwọn àpéjọ wa. Kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn típàdé bá parí tàbí lásìkò ìsinmi, a lè bá àwọn tá ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ ká lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa. (2Kọ 6:13) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè wá di ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́, tí àá sì jọ wà títí láé! Ju gbogbo ẹ̀ lọ, táwọn míì bá rí bá a ṣe ń fìfẹ́ tòótọ́ hàn síra wa, àwọn náà lè pinnu láti wá sin Jèhófà.—Jo 13:35.
WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀPÉJỌ ÀGBÁYÉ “ÌFẸ́ KÌ Í YẸ̀ LÁÉ”! KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo làwọn ará ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì nígbà àpéjọ àgbáyé ọdún 2019?
-
Kí nìdí tí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà fi ṣàrà-ọ̀tọ̀?
-
Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn táwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí mẹ́nu kàn?
-
Báwo làwọn ará ṣe fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn lórílẹ̀-èdè Jámánì àti South Korea?
-
Kí la pinnu láti túbọ̀ máa ṣe?