MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Pinnu Láti Sin Jèhófà
Ṣé ọ̀dọ́ àbí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ò tíì ṣèrìbọmi ni ẹ́, ṣé ó wù ẹ́ kó o ṣèrìbọmi? Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi? Ìdí ni pé ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi máa jẹ́ kó o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Sm 91:1) Ó tún máa jẹ́ kó o rí ìgbàlà. (1Pe 3:21) Kí ló máa jẹ́ kó o tóótun láti ṣèrìbọmi?
Ṣe ohun tá á mú kó dá ẹ lójú pé òótọ́ lohun tó ò ń kọ́. Tí nǹkan bá rú ẹ lójú, gbìyànjú láti ṣèwádìí nípa ẹ̀. (Ro 12:2) Tó o bá rí ohun tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí, tètè ṣàtúnṣe torí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà. (Owe 27:11; Ef 4:23, 24) Gbogbo ìgbà ni kó o máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, á sì fún ẹ lókun. (1Pe 5:10, 11) Ohunkóhun tó o bá ṣe láti sin Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìjọsìn Jèhófà lohun tó dáa jù lọ téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe!—Sm 16:11.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ BÓ O ṢE LÈ ṢÈRÌBỌMI, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Ìṣòro wo làwọn kan ti borí kí wọ́n lè tóótun láti ṣèrìbọmi?
-
Kí lo lè ṣe tá á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára kó o lè ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà?
-
Kí ló mú káwọn kan pinnu láti ṣèrìbọmi?
-
Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó bá pinnu pé òun làwọn máa sìn?
-
Kí ni ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?