ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Iṣẹ́ Ìsìn Àwọn Ọmọ Léfì
Jèhófà yan ẹ̀yà Léfì láti rọ́pò àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Nọ 3:11-13; it-2 683 ¶3)
Iṣẹ́ ìsìn tó ṣeyebíye làwọn ọmọ Léfì ń ṣe (Nọ 3:25, 26, 31, 36, 37; it-2 241)
Àwọn ọmọ Léfì tó wà láàárín ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ni wọ́n máa ń yàn láti ṣiṣẹ́ (Nọ 4:46-48; it-2 241)
Àwọn ọkùnrin tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Áárónì nìkan ló ń ṣiṣẹ́ àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì tó kù sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Bó ṣe rí nínú ìjọ lónìí nìyẹn, àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ń ṣiṣẹ́ kára gan-an, àwọn arákùnrin tó kù sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.