February 22-28
NỌ́ŃBÀ 5-6
Orin 81 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Báwo Lo Ṣe Lè Fìwà Jọ Àwọn Násírì?”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Nọ 6:6, 7—Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Sámúsìn ṣì jẹ́ Násírì lẹ́yìn tó fọwọ́ kan òkú èèyàn àti tẹran tó pa? (w05 1/15 30 ¶2)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Nọ 5:1-18 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Ta Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó) (th ẹ̀kọ́ 1)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fún onílé ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 3)
Àsọyé: (5 min.) w06 1/15 32—Àkòrí: Ohun Pàtàkì Kan Tó Túbọ̀ Jẹ́rìí Sí I Pé Ìwé Tó Ti Pẹ́ Ni Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ṣé Wàá Fẹ́ Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣù March Tàbí April?”: (5 min.) Ìjíròrò.
A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pe Àwọn Èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi ní Saturday, February 27: (10 min.) Ìjíròrò. Fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìwé ìkésíni náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Sọ ètò tí ìjọ ṣe láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a máa lò. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará pé: Ìgbà wo ló yẹ ká fi fídíò Ìrántí Ikú Jésù han onílé? Báwo la ṣe lè mọ̀ tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 5 ¶9-16
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 36 àti Àdúrà