Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Fẹ́ Ká Wàásù fún Gbogbo Èèyàn

Jèhófà Fẹ́ Ká Wàásù fún Gbogbo Èèyàn

Bí Jèhófà ṣe mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà létòlétò, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe fẹ́ ká wà létòlétò lónìí ká lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kárí ayé, gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì, àyíká, ìjọ àtàwọn àwùjọ kéékèèké ló ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí ìhìn rere náà lè máa tẹ̀ síwájú. Gbogbo èèyàn là ń wàásù fún, kódà a tún máa ń wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa.​—Ifi 14:6, 7.

Ṣé ìwọ náà lè kọ́ èdè míì kó o lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́? Kódà tí ò bá rọrùn fún ẹ láti ya àkókò sọ́tọ̀ kó o lè kọ́ èdè míì, o lè lo ètò ìṣiṣẹ́ JW Language láti kọ́ bó o ṣe lè fi èdè míì wàásù lọ́nà tó rọrùn. Tó o bá lo ọ̀nà yìí, ó dájú pé ìwọ náà máa láyọ̀ bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n fi oríṣiríṣi èdè wàásù “àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run,” tí wọ́n sì rí bí inú àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn ṣe ń dùn.​—Iṣe 2:7-11.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ​—MÁA WÀÁSÙ FÚN ÀWỌN TÓ Ń SỌ ÈDÈ MÍÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ìgbà wo lo lè lo ètò ìṣiṣẹ́ JW Language?

  • Àwọn nǹkan wo ló wà lórí ètò ìṣiṣẹ́ yìí?

  • Ó yẹ kí gbogbo èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè gbọ́ ìhìn rere

    Oríṣiríṣi èdè wo ni wọ́n ń sọ lágbègbè yín?

  • Kí lo lè ṣe tí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o fẹ́ sọ ò bá gbọ́ èdè rẹ?​—od 100-101 ¶39-41