Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣe Ohun Tá Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I

Ṣe Ohun Tá Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I

Jèhófà ò fọwọ́ kékeré mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Ó sọ pé àwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ ṣe ara wọn lọ́kan. (Mt 19:5, 6) Láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn, torí kò sí ìgbéyàwó tó dáa tán. Tí ìṣòro bá dé, àwọn kan gbà pé ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀ ló máa yanjú ìṣòro náà, àmọ́ àwa Kristẹni ò gbọ́dọ̀ gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè. Kí ni tọkọtaya lè ṣe láti mú kí ìgbéyàwó wọn lágbára sí i?

Ohun márùn-ún yìí ṣe pàtàkì.

  1. Má ṣe máa tage pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ, bákàn náà yẹra fún eré ìnàjú tó lè gbé ìṣekúṣe sí ẹ lọ́kàn, torí wọ́n lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó rẹ.​—Mt 5:28; 2Pe 2:14.

  2. Jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ máa lágbára sí i, kó o sì pinnu pé wàá túbọ̀ máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.​—Sm 97:10.

  3. Máa sapá kí ìwà ẹ lè dáa sí i, kó o sì máa ṣe àwọn nǹkan kéékèèké láti ran ẹnì kejì rẹ lọ́wọ́.​—Kol 3:8-10, 12-14.

  4. Ẹ máa bá ara yín sọ̀rọ̀ déédéé, kẹ́ ẹ sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.​—Kol 4:6.

  5. Máa fìfẹ́ hàn sí ẹnì kejì rẹ déédéé, má sì máa ro tara ẹ nìkan tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.​—1Kọ 7:3, 4; 10:24.

Bí àwa Kristẹni ṣe ń fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó, ṣe là ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀.

WO FÍDÍÒ NÁÀ A GBỌ́DỌ̀ ‘FI ÌFARADÀ SÁRÉ’​—MÁA TẸ̀ LÉ ÒFIN ERÉ SÍSÁ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó lè dùn níbẹ̀rẹ̀, àwọn ìṣòro wo ló ṣì lè yọjú?

  • Báwo ni ìlànà Bíbélì ṣe lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ tó bá ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́?

  • Máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kí ìgbéyàwó rẹ lè láyọ̀

    Àwọn ìlànà wo ni Jèhófà fẹ́ kí tọkọtaya máa tẹ̀ lé?

  • Kí ìgbéyàwó tó lè láyọ̀, kí ni tọkọtaya gbọ́dọ̀ máa ṣe?