ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ọdún Júbílì Ṣàpẹẹrẹ Òmìnira Ọjọ́ Iwájú
Ọdún Júbílì máa ń jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́ àti òṣì (Le 25:10; it-1 871; wo àwòrán iwájú ìwé)
Wọn kì í ta ilẹ̀ wọn, ṣe ni wọ́n máa ń yá ara wọn nílẹ̀, bí ilẹ̀ náà bá ṣe dáa sí ni wọ́n fi máa ń ṣírò iye tí wọ́n máa dá lé e (Le 25:15; it-1 1200 ¶2)
Jèhófà máa ń bù kún wọn tí wọ́n bá pa òfin Júbílì mọ́ (Le 25:18-22; it-2 122-123)
Láìpẹ́, àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ máa gbádùn Júbílì ìṣàpẹẹrẹ ní kíkún nígbà tí Ọlọ́run bá fún wọn ní òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Ro 8:21.
Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ká lè gbádùn òmìnira tí Ọlọ́run ṣèlérí?