MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ọlọ́run àti Kristi Jẹ́ Kí Òmìnira Ọjọ́ Iwájú Ṣeé Ṣe
Ìṣòro wo lò ń bá yí lójoojúmọ́? Ṣé olórí ìdílé tó ní ojúṣe tó pọ̀ ni ẹ́? Ṣé òbí tó ń dá tọ́mọ ni ẹ́, tí ò sì rọrùn fún ẹ láti gbọ́ bùkátà? Ṣé ọmọ ilé ìwé ni ẹ́, táwọn tẹ́ ẹ jọ wà nílé ìwé sì ń halẹ̀ mọ́ ẹ? Ṣé àìlera rẹ ló mú kí nǹkan nira fún ẹ àbí o ò lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ mọ́ torí ara tó ń dara àgbà? Kò sẹ́ni tí ò níṣòro tó ń bá yí. Kódà ìṣòro ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa pọ̀ gan-an. Àmọ́, ó dá wa lójú pé a máa bọ́ láìpẹ́.—2Kọ 4:16-18.
Bá a ṣe ń retí àsìkò yẹn, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tójú wa ń rí, ó mọyì bá a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin tá à ń fara dà á, ó sì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó fẹ́ fún wa lọ́jọ́ iwájú. (Jer 29:11, 12) Jésù náà nífẹ̀ẹ́ wa. Ó fẹ́ ká fọkàn balẹ̀ bá a ṣe ń sin Jèhófà nìṣó, torí ó sọ fún wa pé: “Mo wà pẹ̀lú yín.” (Mt 28:20) Tá a bá fara balẹ̀ ronú nípa òmìnira tá a máa ní lọ́jọ́ iwájú nínú Ìjọba Ọlọ́run, ìrètí wa á dájú, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú.—Ro 8:19-21.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ BÍ ÌJÌ BÁ Ń JÀ, JÉSÙ NI KÓ O TẸJÚ MỌ́!—ÀPẸẸRẸ ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ ỌJỌ́ Ọ̀LA, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo làwa èèyàn ṣe di àjèjì sí Ọlọ́run, kí nìyẹn sì yọrí sí?
-
Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn olóòótọ́ lọ́jọ́ iwájú?
-
Kí ló mú káwọn ìlérí yìí ṣeé ṣe?
-
Èwo lára àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ṣèlérí lọ́jọ́ iwájú ló wù ẹ́ jù?