MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Rí I Pé Ẹ̀ Ń Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín
Lónìí, àwọn èèyàn gbà pé ohun tó dára burú, ohun tó burú sì dára. (Ais 5:20) Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ fi ń ṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí, irú bíi kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀. Àwọn kan nílé ìwé lè máa fúngun mọ́ àwọn ọmọ wa láti hùwà àìtọ́. Báwo lo ṣe lè múra ọkàn àwọn ọmọ rẹ sílẹ̀ láti borí ìṣòro yìí tàbí èyí tó ṣeé ṣe kó yọjú lọ́jọ́ iwájú?
Máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Le 18:3) Máa kọ́ wọn ní ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀, kó o sì rí i pé ohun tó ò ń kọ́ wọn bá ọjọ́ orí wọn mu. (Di 6:7) Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo ti kọ́ ọmọ mi bó ṣe yẹ kó máa bá àwọn míì ṣeré lọ́nà tí ò fi ní gbé èròkerò síni lọ́kàn? Ṣé mo ti jẹ́ kó mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn máa wọ aṣọ tó bójú mu àti ohun tó yẹ kó ṣe tẹ́nì kan bá fẹ́ fọwọ́ kàn án lọ́nà tí kò tọ́? Tẹ́nì kan bá fẹ́ fi àwòrán ìṣekúṣe han ọmọ mi tàbí tí wọ́n bá ní kó ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra, ṣé ó mọ ohun tó yẹ kó ṣe?’ Tó o bá ti kọ́ wọn ní ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọn ò ní kó sínú ìṣòro. (Owe 27:12; Onw 7:12) Bó o ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì ẹ̀bùn tí Jèhófà fún ẹ.—Sm 127:3.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KỌ́ ILÉ TÓ MÁA WÀ PẸ́ TÍTÍ—DÁÀBÒ BO ÀWỌN ỌMỌ RẸ LỌ́WỌ́ “OHUN BÚBURÚ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí nìdí tí kò fi rọrùn fáwọn òbí kan láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀?
-
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn ní “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà”?—Ef 6:4
-
Àwọn nǹkan wo ni ètò Jèhófà ti ṣe kó lè rọrùn fáwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ìbálòpọ̀?—w19.05 12, àpótí
-
Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ déédéé kí wọ́n má bàa kó sínú ìṣòro?