ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Má Jẹ́ Kí Ohunkóhun Ba Ìwà Mímọ́ Rẹ Jẹ́
Jèhófà fẹ́ kí ìwà wa yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn ayé (Le 18:3; w19.06 27 ¶10)
Jèhófà kórìíra ìwà tó burú jáì, irú bíi bíbá ìbátan ẹni lòpọ̀, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti bíbá ẹranko lòpọ̀ (Le 18:6, 22, 23; w17.02 20 ¶13)
Jèhófà máa pa àwọn tó ń hùwà àìmọ́ yìí run láìpẹ́ (Le 18:24, 25; Owe 2:22; w14 7/1 7 ¶2)
Sátánì ò fẹ́ ká wọnú ayé tuntun. Àmọ́ àwọn ìlànà Jèhófà lè dáàbò bò wá ká má bàa kó sí pańpẹ́ Sátánì.
Kí la lè ṣe tá á jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a kórìíra ìṣekúṣe?