Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Nígbà Àkọ́kọ́

Ìbéèrè: Ṣé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà?

Bíbélì: Sm 65:2

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Àwọn nǹkan wo la lè bá Ọlọ́run sọ nínú àdúrà?

WÀÁ RÍ ẸSẸ BÍBÉLÌ YÌÍ NÍNÚ ÀPÓTÍ ÌKỌ́NILẸ́KỌ̀Ọ́:

Ìpadàbẹ̀wò

Ìbéèrè: Àwọn nǹkan wo la lè bá Ọlọ́run sọ nínú àdúrà?

Bíbélì: 1Jo 5:14

Ìbéèrè fún ìgbà míì: Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń dáhùn àdúrà wa?

WÀÁ RÍ ẸSẸ BÍBÉLÌ YÌÍ NÍNÚ ÀPÓTÍ ÌKỌ́NILẸ́KỌ̀Ọ́:

Ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi (February 27–March 27)

O lè sọ pé: “A fẹ́ pè yín síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún [o lè pè lórí fóònù tàbí kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́]. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ṣe ìpàdé pàtàkì yìí kárí ayé.” Fún ẹni náà ní ìwé ìkésíni [tàbí kó o fi ránṣẹ́ lórí ìkànnì], kó o wá sọ pé: “Ìwé ìkésíni yìí máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ibi tá a ti fẹ́ ṣe é ládùúgbò wa [tàbí bẹ́ ẹ ṣe lè wò ó lórí ìkànnì] àti àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀. A tún fẹ́ kẹ́ ẹ wá gbọ́ àkànṣe àsọyé kan ní ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi náà.”

Tí Ẹni Náà Bá Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Rẹ, Fi Ìbéèrè Yìí Sílẹ̀: Kí nìdí tí Jésù fi kú?