MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Sámúẹ́lì
Sámúẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. Nígbà tó wà ní kékeré, kò jẹ́ kí Hófínì àti Fíníhásì, ìyẹn àwọn ọmọ Élì kọ́ òun ní ìkọ́kúkọ̀ọ́. (1Sa 2:22-26) Jèhófà wà pẹ̀lú Sámúẹ́lì bó ṣe ń dàgbà. (1Sa 3:19) Kódà nígbà tó dàgbà, ó ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀.—1Sa 8:1-5.
Kí la lè kọ́ lára Sámúẹ́lì? Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ò ń kojú àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Ó lè jẹ́ kó o nígboyà. (Ais 41:10, 13) Tó o bá jẹ́ òbí, tí ọmọ ẹ ò sì ṣe dáadáa ńkọ́? Rántí pé Sámúẹ́lì ò lè fipá mú àwọn ọmọ ẹ̀ tó ti tójú bọ́ láti máa sin Jèhófà. Ó fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti jẹ́ olóòótọ́, kó sì múnú Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run dùn. A ò sì lè sọ, àpẹẹrẹ rẹ lè mú kọ́mọ ẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁRA SÁMÚẸ́LÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe fi hàn pé òun nígboyà nígbà tó wà ní kékeré?
-
Báwo ni Danny ṣe fi hàn pé òun nígboyà?
-
Àpẹẹrẹ rere wo ni Sámúẹ́lì fi lélẹ̀ nígbà tó dàgbà?
-
Àpẹẹrẹ rere wo làwọn òbí Danny fi lélẹ̀?