February 28–March 6
1 SÁMÚẸ́LÌ 9-11
Orin 121 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Sọ́ọ̀lù Nírẹ̀lẹ̀, Ó sì Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ̀ Níbẹ̀rẹ̀”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
1Sa 9:9—Kí ló ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí? (w05 3/15 22 ¶8)
Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) 1Sa 9:1-10 (th ẹ̀kọ́ 5)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
“Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Máa Fún Ẹ Láyọ̀—Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú”: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú.
Àsọyé: (5 min.) w15 4/15 6-7 ¶16-20—Àkòrí: Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́ Ká sì Ṣàṣeyọrí. (th ẹ̀kọ́ 19)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún: (15 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún. Lẹ́yìn náà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 21 ¶7-12
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 123 àti Àdúrà