MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Yín Fáwọn Òbí Yín
Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa sọ tọkàn ẹ fáwọn òbí ẹ? (Owe 23:26) Ìdí ni pé Jèhófà ló ní kí wọ́n máa bójú tó ẹ, kí wọ́n sì máa tọ́ ẹ sọ́nà. (Sm 127:3, 4) Àmọ́, kò sí bí wọ́n ṣe fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí o ò bá jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó ò ń bá yí, o ò sì ní lè jàǹfààní látinú ìrírí wọn. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo nǹkan lo gbọ́dọ̀ máa sọ fáwọn òbí ẹ? Kò pọn dandan kó rí bẹ́ẹ̀, tó ò bá ṣáà ti fi àwọn ohun tí kò yẹ pa mọ́.—Owe 3:32.
Báwo lo ṣe lè bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀? O lè wá àkókò tó máa rọrùn fún wọn, táá sì rọrùn fún ìwọ náà. Tí ìyẹn ò bá rọrùn, o lè kọ lẹ́tà sí ọ̀kan nínú wọn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ. Àmọ́ tí wọ́n bá béèrè ohun tí o ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ ńkọ́, kí lo lè ṣe? Má gbàgbé pé àwọn òbí ẹ fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni. Fi sọ́kàn pé ọ̀rẹ́ ẹ ni wọ́n jẹ́, wọn kì í ṣe ọ̀tá. Tó o bá ń sapá láti máa sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fáwọn òbí ẹ, ó dájú pé ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ máa ṣe ẹ́ láǹfààní nísinsìnyí àti títí láé!—Owe 4:10-12.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÀ Ọ̀DỌ́ MI—BÁWO NI MO ṢE LÈ MÁA BÁ ÀWỌN ÒBÍ MI SỌ̀RỌ̀ KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ni Esther àti Partik rí i pé àwọn ń ṣe tí ò dáa?
-
Kí lo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?
-
Kí làwọn òbí ẹ ti ṣe fún ẹ tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ?
-
Àwọn ìlànà Bíbélì wo lo lè ronú lé tó bá ṣòro fún ẹ láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rò?