MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Wa Lójú Pé Ọlọ́gbọ́n Ni
Ṣé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń mọ ohun tó dáa jù fún wa? Bẹ́ẹ̀ ni! Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu fún wa ni pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. (Owe 16:3, 9) Àmọ́ nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tí ohun tí Jèhófà sọ bá yàtọ̀ sí èrò wa. Tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, á túbọ̀ dá wa lójú pé ọgbọ́n rẹ̀ ò láfiwé.—Owe 30:24, 25; Ro 1:20.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ? BÁWO NI ÀWỌN ÈÈRÀ ṢE Ń RÌN LÁÌSÍ SÚN KẸẸRẸ FÀ KẸẸRẸ? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí làwọn èèrà sábà máa ń ṣe lójoojúmọ́?
-
Kí làwọn èèrà máa ń ṣe kó má bàa sí sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ?
-
Kí làwa èèyàn lè rí kọ́ látinú bí àwọn èèrà ṣe ń rìn láìsí sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ? BÍ OYIN ṢE Ń FÒ LÁÌKA ATẸ́GÙN TÓ LE SÍ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Ìṣòro wo làwọn tó ń wa ọkọ̀ òfuurufú kékeré máa ń ní?
-
Kí làwọn oyin máa ń ṣe tí wọ́n bá ń fò tí atẹ́gùn kì í fi í gbé wọn kiri?
-
Kí làwọn èèyàn ń ronú láti ṣe lọ́jọ́ iwájú bí wọ́n ṣe ń wo ọ̀nà tí oyin gbà ń fò?
Àwọn nǹkan wo lò ń rí láyìíká rẹ tó jẹ́ kó o gbà pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà