Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Ẹ Kò Ní Yẹ̀ Láé

Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Ẹ Kò Ní Yẹ̀ Láé

Kò sí àní-àní pé o ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. (Ais 43:4) Ó fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀, ó sì mú kó o wà nínú ètò rẹ̀. Bó o ṣe ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi ti mú kó o di ti Jèhófà. Torí náà, ó máa tójú ẹ torí pé àyànfẹ́ rẹ̀ lo jẹ́. Kódà, kò ní fi ẹ́ sílẹ̀ lásìkò tó o bá kojú ìṣòro. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa lo ètò rẹ̀ láti fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹ.​—Sm 25:10.

Tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí ètò Jèhófà ń ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa lónìí.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌRÒYÌN IṢẸ́ ÌGBÌMỌ̀ OLÙṢEKÒKÁÁRÍ 2019, LẸ́YÌN NÁÀ Ẹ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ètò wo ni Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí sọ pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan ṣe láti pèsè ìrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?

  • Báwo ni ètò Jèhófà ṣe pèsè ìrànwọ́, tí wọ́n sì fún àwọn ará nítọni nígbà tí àjálù ṣẹlẹ̀ ní Indonẹ́ṣíà àti Nàìjíríà?

  • Kí ló wú ẹ lórí nínú ohun tí ètò Ọlọ́run ṣe lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Corona?