MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Fi Ìlànà Bíbélì Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọn Lè Ṣàṣeyọrí
Àwọn òbí Kristẹni fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn láyọ̀ kí wọ́n sì gbádùn iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí tí wọ́n bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì kọ́ wọn.—Owe 22:6.
-
Jẹ́ kó rọrùn fún àwọn ọmọ rẹ láti bá ẹ sọ̀rọ̀.—Jem 1:19
-
Fi àpẹẹrẹ tó dáa lé lẹ̀ fún wọn.—Di 6:6
-
Máa kópa nínú ìjọsìn Jèhófà déédéé.—Ef 6:4
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KỌ́ ILÉ TÓ MÁA WÀ PẸ́ TÍTÍ—Ẹ TỌ́ ÀWỌN ỌMỌ YÍN ‘NÍ Ọ̀NÀ TÍ WỌN YÓÒ TỌ̀,’ KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè fòye bá àwọn ọmọ yín lò?
-
Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè fi ìlànà tó wà ní Jémíìsì 1:19 sílò?
-
Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe tí ìṣòro bá yọjú?