MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi?
Lọ́dọọdún, àwa èèyàn Jèhófà máa ń fojú sọ́nà láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi pa pọ̀. Láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa ń lo àǹfààní yẹn láti yin Jèhófà ká sì dúpẹ́ fún ẹ̀bùn ìràpadà tó fún wa. (Ef 1:3, 7) Bí àpẹẹrẹ, a máa ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Láwọn oṣù March tàbí April ọ̀pọ̀ máa ń ṣètò àkókò wọn láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, wọ́n á sì láǹfààní láti ròyìn ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákátì. Ṣé o lè fi kún àkókò tó ò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí? Báwo lo ṣe lè ṣe é?
Òótọ́ kan ni pé, a lè ṣàṣeyọrí tá a bá múra sílẹ̀. (Owe 21:5) Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ bí ọjọ́ náà ṣe ń sún mọ́. Ronú nípa bó o ṣe lè fi kún àkókò tó o máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì pinnu ohun tó o lè ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àfojúsùn náà. Lẹ́yìn náà, bẹ Jèhófà pé kó bù kún ìsapá ẹ.—1Jo 5:14, 15.
Ṣé o lè ronú àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí?