Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Sapá Láti Mọ Èrò Ọlọ́run

Sapá Láti Mọ Èrò Ọlọ́run

A máa ń fẹ́ múnú Jèhófà dùn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. (Owe 27:11) Àmọ́ nígbà míì, a lè fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ kan, kó sì jẹ́ pé kò sí ìlànà kan pàtó lórí ọ̀rọ̀ náà. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tó bá èrò Ọlọ́run mu lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀?

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Ní gbogbo ìgbà tá a bá ń ka Bíbélì, ṣe ló dà bíi pé à ń lo àkókò wa pẹ̀lú Jèhófà. A lè mọ èrò Jèhófà tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò bó ṣe bá àwọn èèyàn ẹ̀ lò láyé àtijọ́, tá a sì tún ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn tó kà sí olóòótọ́ àti aláìṣòótọ́. Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, ẹ̀mí mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ kà lé rántí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì àti àwọn ìlànà tá a ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Jo 14:26.

Máa ṣèwádìí. Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu, o lè bi ara ẹ pé, ‘Àwọn ẹsẹ tàbí ìtàn inú Bíbélì wo ló lè ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ èrò Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà?’ Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bákan náà, àwọn ohun èlò ìwádìí tó wà ní èdè rẹ tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò ẹ mu.—Sm 25:4.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ A GBỌ́DỌ̀FI ÌFARADÀ SÁRÉ’—MÁA JẸ OÚNJẸ TÓ Ń ṢARA LÓORE, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ipò tó nira wo ni ọ̀dọ́bìnrin tó wà nínú fídíò yìí kojú nílé ìwé?

  • Báwo lo ṣe lè lo àwọn ohun èlò ìwádìí tó o bá kojú irú ìṣòro yìí?

  • Báwo ni ìwádìí àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání?—Heb 5:13, 14