Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Tó O Ní Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Túbọ̀ Lágbára

Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Tó O Ní Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Túbọ̀ Lágbára

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè tún ayé wa ṣe. (Heb 4:12) Àmọ́ ká tó lè jàǹfààní látinú àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹ̀, àfi kó dá wa lójú pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni lóòótọ́. (1Tẹ 2:13) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Bíbélì lágbára sí i?

Máa ka apá kan nínú Bíbélì lójoojúmọ́. Bó o ṣe ń kà á, máa kíyè sí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ni òǹṣèwé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fara balẹ̀ wo àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Òwe, wàá rí i pé ó ṣì wúlò lákòókò wa yìí.​—Owe 13:20; 14:30.

Ṣètò láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sapá láti mọ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì. Nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àkòrí náà “Bíbélì” lẹ́yìn náà “Bíbélì Ní Ìmísí Ọlọ́run.” Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni tó wà ní Àfikún A3 nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Bíbélì ò tíì yí pa dà.

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ ÌDÍ TÁ A FI GBÀ GBỌ́ PÉ . . . Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NI BÍBÉLÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ TẸ̀ LÉ E YÌÍ:

  • Báwo ni ògiri tẹ́ńpìlì tí wọ́n ṣàwárí ní ìlú Karnak, lórílẹ̀-èdè Íjíbítì ṣe jẹ́ ká gbà pé òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ò tíì yí pa dà?

  • Báwo ni bí Bíbélì ṣe wà títí di àkókò wa yìí ṣe fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni lóòótọ́?​—Ka Àìsáyà 40:8