Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún Ìtọ́jú Pàjáwìrì

Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún Ìtọ́jú Pàjáwìrì

Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tá ò lérò lè ṣẹlẹ̀ tó lè mú ká dèrò ilé ìwòsàn. Torí náà, ìsinsìnyí ni kó o ti múra sílẹ̀ kó o sì tún ṣètò tó bá yẹ kí ohun tá ò lérò tó ṣẹlẹ̀. Ìyẹn máa fi hàn pé ẹ̀mí jọ ẹ́ lójú, o sì ka òfin Jèhófà nípa ẹ̀jẹ̀ sí.​—Iṣe 15:28, 29.

Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀?

  • Gbàdúrà, kó o sì fara balẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ kún káàdì DPA rẹ (ìyẹn káàdì tá a fi ń fa àṣẹ ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ìlera lé aṣojú ẹni lọ́wọ́). a Àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi lè gba káàdì DPA lọ́wọ́ ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn, wọ́n sì tún lè gba káàdì ìdánimọ̀ fún àwọn ọmọ wọn kéékèèké

  • Tó o bá lóyún, béèrè fún ìwé Ìsọfúnni fún Àwọn Aláboyún (S-401) lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ rẹ. Ìsọfúnni tó wà nínú ẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ètò tó yẹ, kó o sì pinnu ṣáájú ohun tí wàá ṣe tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ lásìkò tó o lóyún àti nígbà tó o bá fẹ́ bímọ

  • Tí ìtọ́jú tó o fẹ́ gbà bá máa la iṣẹ́ abẹ lọ tàbí tó bá máa mú kí wọ́n dá ẹ dúró sílé ìwòsàn, jọ̀wọ́ sọ fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ ṣáájú, kó o sì sọ fún àwọn tó ń bójú tó ilé ìwòsàn náà pé wàá fẹ́ kí ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹ

Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá fẹ́ kọ ọ̀rọ̀ kún káàdì DPA rẹ. Àmọ́, àwọn alàgbà ò ní ṣe ìpinnu èyíkéyìí fún ẹ nípa irú ìtọ́jú tó yẹ kó o gbà, torí ìpinnu ara ẹni nìyẹn. (Ro 14:12; Ga 6:5) Bákan náà, tó o bá dojú kọ ipò tó ṣeé ṣe kó la ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ lọ, sọ fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ, wọ́n á bá ẹ kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC).

Báwo ni Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ètò Ọlọ́run ti dá àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ fún àwọn dókítà àti àwọn amòfin. Wọ́n lè jíròrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwọn dókítà tó ń tọ́jú ẹ. Wọ́n sì tún lè bá ẹ wá dókítà tó máa gbà láti tọ́jú ẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.

Ẹ WO FÍDÍÒ BÁ A ṢE LÈ ṢE ÌPINNU TÓ BỌ́GBỌ́N MU LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ Ẹ̀JẸ̀, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Nínú fídíò yìí, kí lo lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ tí ìtọ́jú pàjáwìrì tó lè la ẹ̀jẹ̀ lọ bá ṣẹlẹ̀?

a Ẹ̀kọ́ 39 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ ìtọ́jú tó la ẹ̀jẹ̀ lọ.