MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Lákòókò Ìṣòro
Onírúurú ìṣòro là ń dojú kọ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ó sì lè máa ṣe wá bíi pé bóyá la máa lè fara dà á torí bí àwọn ìṣòro náà ṣe pọ̀ tó. Àmọ́, tá a bá sún mọ́ Jèhófà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro tá a tiẹ̀ rò pé ó le gan-an. (Ais 43:2, 4) Báwo la ṣe lè sún mọ́ Jèhófà tá a bá wà nínú ìṣòro?
Máa Gbàdúrà. Tá a bá tú ọkàn wa jáde sí Jèhófà nínú àdúrà, ó máa fún wa ní àlàáfíà àti okun ká lè fara dà á.—Flp 4:6, 7; 1Tẹ 5:17.
Máa Lọ Sípàdé. Àsìkò yìí gan-an la nílò àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fún wa láwọn ìpàdé wa, bí oúnjẹ tẹ̀mí àti ìbákẹ́gbẹ́ àwọn ará. (Heb 10:24, 25) Tá a bá ń múra àwọn ìpàdé sílẹ̀, tá à ń pésẹ̀ déédéé, tá a sì ń kópa nínú ẹ̀, a máa rí bí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́.—Ifi 2:29.
Máa Kópa Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù. Tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àá lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Àá tún ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àti àwọn ará wa.—1Kọ 3:5-10.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ MÁA FÀ Ẹ́ MỌ́RA, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ló ran Malu lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nígbà tó kojú ìṣòro?
-
Bíi ti Malu, báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 34:18 ṣe lè tù wá nínú tá a bá kojú ìṣòro?
-
Báwo ni ìrírí Malu ṣe fi hàn pé Jèhófà ń fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” lásìkò wàhálà?—2Kọ 4:7