Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Kó O Lè Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Tó Le Gan-an

Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Kó O Lè Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Tó Le Gan-an

Iṣẹ́ pàtàkì ni iṣẹ́ aṣọ́bodè tí àwọn ọmọ Léfì ń ṣe (1Kr 9:26, 27; w05 10/1 9 ¶8)

Fíníhásì ni olórí àwọn aṣọ́bodè àgọ́ ìjọsìn nígbà ayé Mósè (1Kr 9:17-20a)

Jèhófà ran Fíníhásì lọ́wọ́ kó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ (1Kr 9:20b; w11 9/15 32 ¶7)

Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ pàtàkì ni Jèhófà fún àwa náà láti ṣe. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò mọ bó o ṣe máa ṣe iṣẹ́ kan, gbàdúrà sí Jèhófà kó o sì sọ fún Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. —Flp 2:13.