ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi kìlọ̀ fún àwọn èèyàn Júdà pé òun máa kọ̀ wọ́n tí wọn ò bá jáwọ́ nínú ìwà búburú wọn (2Ọb 24:2, 3; w01 2/15 12 ¶2)
Jèhófà lo àwọn ará Bábílónì láti pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣ.S.K. (2Ọb 25:8-10; w07 3/15 11 ¶10)
Jèhófà dáàbò bo àwọn tó fetí sí ìkìlọ̀ rẹ̀ (2Ọb 25:11)
Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé òun máa mú ìdájọ́ wá sórí “àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.”—2Pe 3:7.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé mò ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ìkìlọ̀ Jèhófà?’—2Ti 4:2.