February 12-18
SÁÀMÙ 5-7
Orin 118 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Jẹ́ Olóòótọ́ Láìka Ohun Táwọn Míì Bá Ṣe Sí
(10 min.)
Àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì jẹ́ kí ohun táwọn míì ṣe kó ẹ̀dùn ọkàn bá a (Sm 6:6, 7)
Ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ (Sm 6:2, 9; w21.03 15 ¶7-8)
Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ìyẹn sì mú kó jẹ́ olóòótọ́ (Sm 6:10)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ǹjẹ́ mò ń sapá kí ìgbàgbọ́ mi lè lágbára débi tí màá fi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ohun táwọn míì bá ṣe sí?’—w20.07 8-9 ¶3-4.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 5:9—Báwo ni ọ̀fun àwọn ẹni burúkú ṣe dà bíi sàréè tó ṣí sílẹ̀? (it-1 995)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 7:1-11 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Wá ọ̀nà tó o lè gbà jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ láìjẹ́ pé o mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
6. Pa Dà Lọ
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà fẹ́ máa bá ẹ jiyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)
7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(4 min.) Àṣefihàn. ijwfq 64—Àkòrí: Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Fi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Kọ̀ Láti Ka Ẹ̀jẹ́ Tàbí Kọ Orin Orílẹ̀-Èdè? (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
Orin 99
8. Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún
(15 min.) Ìjíròrò. Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún, jẹ́ kí àwọn ará sọ àwọn ohun tó wú wọn lórí nínú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé ti Ọdún 2023. Lẹ́yìn náà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 5 ¶16-22, àpótí ojú ìwé 42