Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

February 19-25

SÁÀMÙ 8-10

February 19-25

Orin 2 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Jèhófà, Màá Fi Gbogbo Ọkàn Mi Yìn Ọ́”!

(10 min.)

Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ò ṣeé díwọ̀n rárá (Sm 8:3-6; w21.08 3 ¶6)

À ń yin Jèhófà tá a bá ń fayọ̀ sọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fáwọn èèyàn (Sm 9:1; w20.05 23 ¶10)

A tún ń yìn ín tá a bá ń fayọ̀ kọrin látọkàn wá (Sm 9:2; w22.04 7 ¶13)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn ọ̀nà míì wo ni mo lè gbà yin Jèhófà?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 8:3—Kí ni onísáàmù náà ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ìka Ọlọ́run? (it-1 832)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, ẹni náà sọ fún ẹ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Àmọ́, ó fẹ́ gbọ́ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà. (th ẹ̀kọ́ 7)

6. Àsọyé

(5 min.) w21.06 6-7 ¶15-18—Àkòrí: Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Yin Jèhófà. (th ẹ̀kọ́ 10)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 10

7. Bá A Ṣe Lè Máa Sọ̀rọ̀ Fàlàlà Tá A Bá Ń Wàásù Láìjẹ́ Bí Àṣà

(10 min.) Ìjíròrò.

Ohun kan tá a lè ṣe táá mú ká túbọ̀ máa yin Jèhófà ni pé ká máa wàásù fáwọn tá a bá bá pàdé lójoojúmọ́. (Sm 35:28) Ẹ̀rù lè kọ́kọ́ bà wá láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà. Torí náà, tá a bá kọ́ bá a ṣe lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ fàlàlà, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà. Kódà, àá gbádùn ẹ̀.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Múra Tán Láti Kéde “Ìhìn Rere Àlàáfíà”—Máa Lo Àǹfààní Tó Bá Yọ. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

Kí lo kọ́ nínú fídíò yìí tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ já fáfá tó bá di pé ká wàásù láìjẹ́ bí àṣà?

Àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọ bó o ṣe lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ fàlàlà:

  •   Máa lo àǹfààní tó bá yọ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nígbàkigbà tó o bá ti jáde nílé. Gbàdúrà, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o pàdé àwọn tó ṣe tán láti gbọ́rọ̀ ẹ

  •   Tó o bá pàdé ẹnì kan, fìfẹ́ hàn sí i, kó o sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tura. Máa kíyè sí irú ẹni tó jẹ́, kó o lè mọ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó máa nífẹ̀ẹ́ sí

  •   Tó bá ṣeé ṣe, gba nọ́ńbà ẹ̀ tàbí àwọn ìsọfúnni míì tó o lè fi kàn sí i

  •   Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò ráyè wàásù tí ìjíròrò yín fi parí, má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ

  •   Máa ronú nípa ẹni náà lẹ́yìn ìjíròrò yín. Máa fi ìlujá ẹsẹ Bíbélì tàbí ti àpilẹ̀kọ orí ìkànnì jw.org ránṣẹ́ sí i, ìyẹn á fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ jẹ ẹ́ lógún

Gbìyànjú èyí wò: Tẹ́nì kan bá kí ẹ pé, ‘Ẹ kú ìsinmi àná, ṣé ẹ gbádùn ẹ̀?’ O lè sọ ohun kan tó o kọ́ nípàdé tàbí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(5 min.)

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 65 àti Àdúrà