Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

February 26–March 3

SÁÀMÙ 11-15

February 26–March 3

Orin 139 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Fojú Inú Wo Ara Rẹ Nínú Ayé Tuntun Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

(10 min.)

Bí àwọn èèyàn ò ṣe tẹ̀ lé òfin ìlú ló mú kí ìwà ipá pọ̀ lónìí (Sm 11:2, 3; w06 5/15 18 ¶3)

Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa tó fòpin sí ìwà ipá (Sm 11:5; wp16.4 11)

Tó o bá ń ronú lórí ìlérí tí Jèhófà ṣe láti gbà wá là, ìyẹn á jẹ́ ká lè fi sùúrù dúró dìgbà tí ayé tuntun máa dé (Sm 13:5, 6; w17.08 7 ¶15)

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ka Ìsíkíẹ́lì 34:25, kó o sì fojú inú wo ara rẹ pé o wà níbi tó tura yìí. —kr 236 ¶16.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 14:1—Báwo ni ìwà yìí ṣe lè kó èèràn ran àwa Kristẹni tòótọ́? (w13 9/15 20 ¶12)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹni náà wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Pe ẹni náà wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)

6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ó wu ẹni náà láti wá sí Ìrántí Ikú Kristi nígbà tá a fún un ní ìwé ìkésíni. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)

7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff kókó pàtàkì ní ẹ̀kọ́ 13, kí lo rí kọ́? àti ohun tó yẹ kó o ṣe. Fi àpilẹ̀kọ kan lápá “Ṣèwádìí” ṣàlàyé fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kó lè lóye ìdí tí Ọlọ́run fi kórìíra ìsìn èké. (th ẹ̀kọ́ 12)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 8

8. “Ọgbọ́n Sàn Ju Àwọn Ohun Ìjà Ogun Lọ”

(10 min.) Ìjíròrò.

Ìwà ipá túbọ̀ ń pọ̀ sí i kárí ayé. Jèhófà mọ̀ pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí lè mú kẹ́rù máa bà wá, ká sì máa kọ́kàn sókè. Ó mọ̀ pé a nílò ohun tó máa dáàbò bò wá. Ohun kan tó sì ń lò láti dáàbò bò wá ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Sm 12:5-7.

Ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì “sàn ju àwọn ohun ìjà ogun lọ.” (Onw 9:18) Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ṣe lè dáàbò bò wá ká má bàa kó sọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn tó kúnnú ayé.

  • Onw 4:9, 10—Má ṣe máa dá wà láwọn ibi tó léwu

  • Owe 22:3—Máa wà lójúfò, kó o sì máa kíyè sí ohun tó ń lọ láyìíká rẹ tó o bá wà níta

  • Owe 26:17—Má ṣe máa dá sí àríyànjiyàn tí kò kàn ẹ́

  • Owe 17:14—Tó o bá rí i pé ìjà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ níbi tó o wà, tètè fi ibẹ̀ sílẹ̀. Bákan náà, tètè kúrò níbi táwọn èèyàn bá ti ń kóra jọ láti wọ́de

  • Lk 12:15—Má ṣe fẹ̀mí ẹ wewu torí pé o fẹ́ dáàbò bo àwọn nǹkan ìní ẹ

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́, Kì Í Ṣe Àwọn Tí Kò Nígbàgbọ́—Tẹ̀ Lé Énọ́kù, Má Tẹ̀ Lé Lámékì. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

Báwo ni àpẹẹrẹ Énọ́kù ṣe ran bàbá yìí lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó dáa lágbègbè táwọn oníwà ipá pọ̀ sí?—Heb 11:5

Láwọn ipò kan, Kristẹni kan lè pinnu pé ó yẹ kí òun ṣe àwọn nǹkan kan láti dáàbò bo ara òun àtàwọn nǹkan ìní òun. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti rí i pé ẹ̀mí èèyàn ò tọwọ́ òun bọ́.—Sm 51:14; wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ July 2017.

9. A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pe Àwọn Èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi ní Saturday, March 2

(5 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ ètò tí ìjọ ṣe láti pín ìwé ìkésíni àti ètò tó wà nílẹ̀ fún àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi. Rán àwọn ará létí pé àwọn akéde tó bá gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti April lè pinnu láti ròyìn wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15).

10. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 6 ¶9-17

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 40 àti Àdúrà