Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

January 1-7

JÓÒBÙ 32-33

January 1-7

Orin 102 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Élíhù ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jóòbù bó ṣe ń sọ ohun tó ń dùn ún

1. Máa Mára Tu Àwọn Tó Ní Ìdààmú Ọkàn

(10 min.)

Máa hùwà pẹ̀lẹ́ sáwọn èèyàn (Job 33:1; it-1 710)

Dípò kó o máa dá wọn lẹ́jọ́, ṣe ni kó o máa fọ̀rọ̀ wọn ro ara ẹ wò (Job 33:6, 7; w14 6/15 25 ¶8-10)

Bíi ti Élíhù, fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, kó o sì ronú kó o tó sọ̀rọ̀ (Job 33:8-12, 17; w20.03 23 ¶17-18; wo àwòrán iwájú ìwé)

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Job 33:25—Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká máa dara wa láàmú torí pé a fẹ́ dán láwọ̀ ju ọjọ́ orí wa lọ? (w13 1/15 19 ¶10)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí—Ohun Tí Jésù Ṣe

(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 1-2.

5. Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3-5 àti apá “Tún Wo.”

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 116

6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(15 min.)

7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 54 àti Àdúrà