January 15-21
JÓÒBÙ 36-37
Orin 147 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ìdí Tá A Fi Gbà Pé Ìlérí Jèhófà Nípa Ìyè Àìnípẹ̀kun Máa Ṣẹ
(10 min.)
Jèhófà wà títí láé (Job 36:26; w15 10/1 13 ¶1-2)
Ọgbọ́n àti agbára tí Jèhófà ní ló mú ká wà láàyè (Job 36:27, 28; w20.05 22 ¶6)
Jèhófà ń kọ́ wa lóhun tá a máa ṣe ká lè wà láàyè títí láé (Job 36:4, 22; Joh 17:3)
Tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ìyè àìnípẹ̀kun, àá lè fara da àwọn ìṣòro wa.—Heb 6:19; w22.10 28 ¶16.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Job 37:20—Báwo ni wọ́n ṣe máa ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? (it-1 492)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Job 36:1-21 (th ẹ̀kọ́ 2)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àsọyé. ijwfq 57 ¶5-15—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ṣenúnibíni Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì? (th ẹ̀kọ́ 18)
Orin 49
7. Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún Ìtọ́jú Pàjáwìrì Tó Lè La Iṣẹ́ Abẹ Lọ
(15 min.) Ìjíròrò. Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí.
Ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká lè pa òfin Ọlọ́run mọ́ tó bá dọ̀rọ̀ lílo ẹ̀jẹ̀. (Iṣe 15:28, 29) Ṣé o máa ń lò wọ́n dáadáa?
Káàdì DPA àti Káàdì Ìdánimọ̀ (ic): Àwọn káàdì méjèèjì yìí máa ń ṣàlàyé ohun tí ẹnì kan fẹ́ tó bá kan ọ̀rọ̀ lílo ẹ̀jẹ̀. Àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi lè gba káàdì DPA fún ìlò ara wọn, wọ́n sì lè gba káàdì ìdánimọ̀ fún àwọn ọmọ wọn kéékèèké. Wọ́n lè gba àwọn káàdì yìí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí àwọn káàdì náà máa wà lọ́wọ́ wa nígbà gbogbo. Má fòní dónìí fọ̀la dọ́la tó o bá fẹ́ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà tàbí tó o bá fẹ́ ṣe ìyípadà sáwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Ìsọfúnni fún Àwọn Aláboyún (S-401) àti Information for Patients Requiring Surgery or Chemotherapy (S-407): Àwọn fọ́ọ̀mù méjèèjì yìí láwọn ìsọfúnni tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè múra sílẹ̀ de irú ìtọ́jú tá a fẹ́, tó fi mọ́ ìpinnu tá a ṣe lórí ọ̀rọ̀ gbígba ẹ̀jẹ̀. Gba àwọn fọ́ọ̀mù yìí lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ rẹ tó o bá lóyún, tó o fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ tàbí tó ń tọ́jú àrùn jẹjẹrẹ.
Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC): Àwọn alàgbà tó kúnjú ìwọ̀n ló wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC), a sì ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ fún àwọn dókítà àtàwọn akéde. Wọ́n lè jíròrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwọn dókítà tó ń tọ́jú ẹ. Wọ́n sì tún lè bá ẹ wá dókítà tó máa gbà láti tọ́jú ẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Kò sì sígbà tó ò lè kàn sí wọn, torí gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Tètè kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) tó o bá rí i pé wọ́n máa dá ẹ dúró sí ilé ìwòsàn tàbí tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ fún ẹ tàbí tí wọ́n fẹ́ tọ́jú ẹ torí àrùn jẹjẹrẹ kódà tó bá dà bíi pé ọ̀rọ̀ náà kò ní la ẹ̀jẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ yìí náà kan àwọn aláboyún. Tó o bá fẹ́ kí ìgbìmọ̀ náà ràn ẹ́ lọ́wọ́, béèrè bó o ṣe lè kàn sí wọn lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ ẹ.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Báwo Ni Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá wà nílé ìwòsàn tàbí tó o bá fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 4 ¶9-12, àpótí tó wà lójú ìwé 34