January 22-28
JÓÒBÙ 38-39
Orin 11 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ṣé O Máa Ń Wáyè Kíyè sí Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Dá?
(10 min.)
Lẹ́yìn tí Jèhófà dá ayé yìí, ó lo àkókò láti yẹ ohun tó ṣe wò (Jẹ 1:10, 12; Job 38:5, 6; w21.08 9 ¶7)
Àwọn áńgẹ́lì fara balẹ̀ wo ohun tí Jèhófà dá (Job 38:7; w20.08 14 ¶2)
Táwa náà bá ń wáyè kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá tá a sì mọyì rẹ̀, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára sí i (Job 38:32-35; w23.03 17 ¶8)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Job 38:8-10—Kí ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kọ́ wa nípa àwọn òfin tí Jèhófà fún wa? (it-2 222)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Job 39:1-22 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ parí ọ̀rọ̀ ẹ nígbà tó o kíyè sí i pé kò wu ẹni náà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, ẹni náà sọ fún ẹ pé èèyàn òun kan kú lẹ́nu àìpẹ́ yìí. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Àsọyé
(5 min.) lmd àfikún A kókó 1—Àkòrí: Àwọn Nǹkan Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Kárí Ayé àti Ìwà Àwọn Èèyàn Fi Hàn Pé Nǹkan Máa Tó Yí Pa Dà. (th ẹ̀kọ́ 16)
Orin 111
7. Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Máa Ń Jẹ́ Ká Rántí Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì
(15 min.) Ìjíròrò.
Nígbà tí Sátánì fojú pọ́n Jóòbù táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí i, àwọn ìṣòro tó dé bá Jóòbù ló gbà á lọ́kàn.
Ka Jóòbù 37:14. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí ló yẹ kí Jóòbù ṣe kó lè máa ronú lọ́nà tó tọ́?
Tá a bá ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà dá nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, ó máa jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe lágbára tó, ìyẹn á sì jẹ́ kó máa wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ sí i, ká sì túbọ̀ nígbàgbọ́ pé ó máa bójú tó wa.—Mt 6:26.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tí Ìwé Jóòbù Kọ́ Wa—Àwọn Ẹranko. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí lo rí nínú fídíò yìí tó lè mú kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 4 ¶13-20