Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

February 10-16

SÁÀMÙ 147-150

February 10-16

Orin 12 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Yin Jèhófà Torí Ọ̀pọ̀ Nǹkan Tó Ń Ṣe

(10 min.)

Ó ń bójú tó wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan (Sm 147:3, 4; w17.07 18 ¶5-6)

Ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ó sì máa ń fi agbára rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ (Sm 147:5; w17.07 18 ¶7)

Ó jẹ́ ká wà lára àwọn èèyàn rẹ̀ (Sm 147:19, 20; w17.07 21 ¶18)


BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn nǹkan míì wo ló mú kó wù mí láti máa yin Jèhófà?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 148:1, 10—Báwo ni àwọn “ẹyẹ abìyẹ́” ṣe ń yin Jèhófà? (w04 6/1 13 ¶ 22)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé àìsàn kan tó lágbára ń ṣe òun. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Lo àǹfààní tó bá yọ láti jẹ́ kẹ́ni náà mọ àwọn ohun tó o kọ́ nípàdé láìpẹ́ yìí. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)

6. Àsọyé

(5 min.) w19.03 10 ¶7-11—Àkòrí: Fetí sí Jésù—Máa Wàásù Ìhìn Rere. Wo àwòrán. (th ẹ̀kọ́ 14)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 159

7. Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún

(15 min.) Ìjíròrò.

Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún. Jẹ́ kí àwọn ará sọ àwọn ohun tó wú wọn lórí nínú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé ti Ọdún 2024. Lẹ́yìn náà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 37 àti Àdúrà