Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

February 17-23

ÒWE 1

February 17-23

Orin 88 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọmọ Sólómọ́nì ń fetí sílẹ̀ bí bàbá ẹ̀ ṣe ń fìfẹ́ gbà á nímọ̀ràn

1. Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ta Lẹ Máa Fetí Sí?

(10 min.)

[Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Òwe.]

Jẹ́ ọlọgbọ́n kó o sì máa fetí sí àwọn òbí ẹ (Owe 1:8; w17.11 29 ¶16-17; wo àwòrán)

Má ṣe fetí sí àwọn tó ń ṣe ohun tí kò dáa (Owe 1:10, 15; w05 2/15 19-20 ¶11-12)

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 1:22—Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “òmùgọ̀,” àwọn wo ló sábà máa ń tọ́ka sí? (it-1 846)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Ẹni náà fẹ́ bá ẹ jiyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Gba nọ́ńbà ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)

6. Pa Dà Lọ

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fún ẹni náà ní káàdì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)

7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 16 kókó 6. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ kan ń ṣiyèméjì pé bóyá làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe wáyé lóòótọ́. Fi àpilẹ̀kọ kan lápá “Ṣèwádìí” ṣàlàyé fún un. (th ẹ̀kọ́ 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 89

8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(15 min.)

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 22 ¶15-21

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 80 àti Àdúrà