February 24–March 2
ÒWE 2
Orin 35 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìdákẹ́kọ̀ọ́?
(10 min.)
Á fi hàn pé o mọyì òtítọ́ (Owe 2:3, 4; w22.08 18 ¶16)
Wàá lè ṣe ìpinnu tó dáa (Owe 2:5-7; w22.10 19 ¶3-4)
Á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára (Owe 2:11, 12; w16.09 23 ¶2-3)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Kí ni mo lè ṣe kí n lè máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Owe 2:1-5—Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà? (bhs orí 19 ¶10)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 2:1-22 (th ẹ̀kọ́ 12)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ bó ṣe lè rí ìsọfúnni tó máa ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fún ẹni náà ní ìwé ìròyìn tó dá lórí ohun tó o kíyè sí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Àsọyé
(5 min.) lmd àfikún A kókó 8—Àkòrí: Ó Yẹ Kí Tọkọtaya Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Wọn. (th ẹ̀kọ́ 13)
Orin 96
7. Ṣé O Máa Ń Walẹ̀ Jìn Kó O Lè Rí Àwọn Ìṣúra Tó Ṣeyebíye?
(15 min.) Ìjíròrò.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ó máa ń wù yín láti wá àwọn ìṣúra tó fara sin? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ wá ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ láyé, ìyẹn ìmọ̀ nípa Ọlọ́run! (Owe 2:4, 5) Tó o bá ń wáyè láti ka Bíbélì lójoojúmọ́, tó ò ń ṣàṣàrò, tó o sì ń walẹ̀ jìn lórí ohun tó o kà, ó dájú pé wàá rí ìṣúra tó ṣeyebíye tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní, wàá sì gbádùn ẹ̀.
-
Tó o bá ń ka Bíbélì, àwọn ìbéèrè wo lo lè bi ara ẹ? (w24.02 32 ¶2-3)
-
Àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣèwádìí?
Àwọn ọ̀wọ́ fídíò Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ọ̀rẹ́ Jèhófà máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà nínú Bíbélì
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Ébẹ́lì
Ka Jẹ́nẹ́sísì 4:2-4 àti Hébérù 11:4. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí ni Ébẹ́lì ṣe tó fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
-
Kí ni Ébẹ́lì ṣe kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ nínú Jèhófà lè túbọ̀ lágbára?
-
Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 23 ¶1-8 àti ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 8