February 3-9
SÁÀMÙ 144-146
Orin 145 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Wọn!”
(10 min.)
Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e (Sm 144:11-15; w18.04 32 ¶3-4)
Ìrètí tá a ní ń múnú wa dùn (Sm 146:5; w22.10 28 ¶16-17)
Títí láé làwọn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn á máa láyọ̀ (Sm 146:10; w18.01 26 ¶19-20)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 145:15, 16—Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, ọwọ́ wo ló yẹ ká fi máa mú àwọn ẹranko? (it-1 111 ¶9)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 144:1-15 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé ọmọ yunifásítì lòun. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi fídíò kan látinú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)
6. Àsọyé
(4 min.) lmd àfikún A kókó 7—Àkòrí: Ó Yẹ Kí Aya Ní Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀ fún Ọkọ Ẹ̀. (th ẹ̀kọ́ 1)
Orin 59
7. Jèhófà Fẹ́ Kó O Máa Láyọ̀
(10 min.) Ìjíròrò.
Ọlọ́run aláyọ̀ ni Jèhófà. (1Ti 1:11) Ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn rere tó fún wa jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká láyọ̀. (Onw 3:12, 13) Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára àwọn ẹ̀bùn yìí, ìyẹn oúnjẹ àti ohùn tó ń tuni lára.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Fẹ́ Ká Máa Yọ̀—Oúnjẹ Aládùn àti Ohùn Tó Ń Tuni Lára. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Báwo ni ẹ̀bùn oúnjẹ àti ohùn tó ń tuni lára tí Jèhófà fún wa ṣe jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó fẹ́ kó o láyọ̀?
Ka Sáàmù 32:8. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Torí o mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kó o láyọ̀, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó túbọ̀ wù ẹ́ láti máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ẹ̀ tó wà nínú Bíbélì àti èyí tí ètò ẹ̀ ń fún wa?
8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(5 min.)
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 22 ¶1-6