January 20-26
SÁÀMÙ 138-139
Orin 93 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Dí Ẹ Lọ́wọ́ Láti Dáhùn Nípàdé
(10 min.)
A fẹ́ máa fi gbogbo ọkàn wa yin Jèhófà (Sm 138:1)
Tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́ láti dáhùn nípàdé, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè nígboyà (Sm 138:3)
Ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ (Sm 138:6; w19.01 10 ¶10)
ÀBÁ: Tí ìdáhùn ẹ bá ṣe ṣókí, ẹ̀rù ò ní bà ẹ́.—w23.04 21 ¶7.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 139:21, 22—Ṣé gbogbo èèyàn làwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa dárí jì? (it-1 862 ¶4)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 139:1-18 (th ẹ̀kọ́ 2)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
5. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 3)
6. Àsọyé
(5 min.) ijwyp àpilẹ̀kọ 105—Àkòrí: Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Tijú Mọ́? (th ẹ̀kọ́ 16)
Orin 59
7. O Lè Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Tó O Bá Tiẹ̀ Ń Tijú
(15 min.) Ìjíròrò.
Ṣé o máa ń tijú? Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o rọra wà láyè ara ẹ? Ṣé àyà ẹ máa ń já tó o bá fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀? Nígbà míì, ìtìjú lè mú kéèyàn má lè ṣe ohun tó wù ú láti ṣe. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń tijú ló ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kí la lè rí kọ́ lára wọn?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Mo Fayé Mi Sin Jèhófà Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Onítìjú. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Báwo ni ìmọ̀ràn tí màmá àgbà fún Arábìnrin Lee pé kó “fayé ẹ̀ sin Jèhófà” ṣe ṣe é láǹfààní?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí Mósè, Jeremáyà àti Tímótì máa tijú. (Ẹk 3:11; 4:10; Jer 1:6-8; 1Ti 4:12) Bó ti wù kó rí, wọ́n gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn. (Ẹk 4:12; Jer 20:11; 2Ti 1:6-8)
Ka Àìsáyà 43:1, 2. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fáwọn tó ń sìn ín?
Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú káwọn tó ń tijú ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lónìí?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Bí Ìrìbọmi Ṣe Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Láyọ̀—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Báwo ni Arábìnrin Jackson ṣe rọ́wọ́ Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
-
Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe lè ran ẹni tó ń tijú lọ́wọ́?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 21 ¶8-13, àpótí ojú ìwé 169