Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

January 27–February 2

SÁÀMÙ 140-143

January 27–February 2

Orin 44 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Ṣe Àwọn Nǹkan Tó Bá Àdúrà Ẹ Mu

(10 min.)

Máa gba ìmọ̀ràn tàbí ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ (Sm 141:5; w22.02 12 ¶13-14)

Máa ronú nípa ohun tí Jèhófà ti ṣe láti gba àwọn èèyàn ẹ̀ là (Sm 143:5; w10 3/15 32 ¶4)

Gbìyànjú láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó (Sm 143:10; w15 3/15 32 ¶2)

Sáàmù 140-143 jẹ́ ká mọ̀ pé Dáfídì ò kàn gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́, ó tún ṣe ohun tó bá àdúrà ẹ̀ mu.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 140:3—Kí nìdí tí Dáfídì ṣe fi ahọ́n àwọn ẹni burúkú wé ti ejò? (it-2 1151)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan lẹ́yìn tó o ṣe ohun kan láti ràn án lọ́wọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Ẹni náà sọ pé ọwọ́ òun dí. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 3)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àṣefihàn. lff ẹ̀kọ́ 39 ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti kókó 1-2—Àkòrí: Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Gba Ẹ̀jẹ̀? (th ẹ̀kọ́ 7)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 141

7. Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún Ìtọ́jú Pàjáwìrì Tàbí Ìtọ́jú Tó Lè La Iṣẹ́ Abẹ Lọ

(15 min.) Ìjíròrò.

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ “tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.” (Sm 46:1) Nǹkan kì í rọrùn rárá lásìkò tá a bá nílò ìtọ́jú nílé ìwòsàn tàbí tí ipò wa tiẹ̀ gba pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún wa. Bó ti wù kó rí, Jèhófà ti pèsè gbogbo ohun tá a nílò, ká lè múra sílẹ̀ fún irú àkókò bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run ti fún wa ní káàdì DPA, káàdì ìdánimọ̀, a àtàwọn ìsọfúnni míì tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. b Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n tún ṣètò àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) táá máa ràn wá lọ́wọ́. Àwọn ohun tí wọ́n ṣe fún wa yìí máa ń jẹ́ ká lè ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run nípa ẹ̀jẹ̀.—Iṣe 15:28, 29.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ṣé O ti Múra Sílẹ̀ De Ìtọ́jú Pàjáwìrì? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Àǹfààní wo làwọn kan ti rí torí pé wọ́n kọ̀rọ̀ sí káàdì DPA wọn?

  • Báwo ni Ìsọfúnni fún Àwọn Aláboyún (S-401) ṣe ran àwọn kan lọ́wọ́?

  • Tá a bá rí i pé wọ́n máa dá wa dúró sílé ìwòsàn tàbí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ fún wa tàbí wọ́n fẹ́ fún wa ní ìtọ́jú tó máa ń gba àkókó irú bí ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ, kí nìdí tó fi yẹ ká tètè kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) kódà tó bá tiẹ̀ dà bíi pé ìtọ́jú náà lè má la ẹ̀jẹ̀ lọ?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 21 ¶14-22

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 103 àti Àdúrà

a Àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi lè gba káàdì DPA fún ara wọn, wọ́n sì lè gba káàdì ìdánimọ̀ fún àwọn ọmọ wọn kéékèèké.

b O lè gba Ìsọfúnni fún Àwọn Aláboyún (S-401), Ìsọfúnni fún Àwọn tó Nílò Iṣẹ́ Abẹ tàbí Ìtọ́jú Chemotherapy (S-407) àti Báwọn Òbí Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wọn Kí Wọ́n Má Bàá Fa Ẹ̀jẹ̀ sí Wọn Lára (S-55) lọ́wọ́ àwọn alàgbà nígbà tó o bá nílò ẹ̀.