Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

January 6-12

SÁÀMÙ 127-134

January 6-12

Orin 134 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Máa Bójú Tó Ẹ̀bùn Iyebíye Tí Jèhófà Fún Yín

(10 min.)

Ẹ̀yin òbí, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà á ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè máa gbọ́ bùkátà ìdílé yín (Sm 127:1, 2)

Àwọn ọmọ jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye látọ̀dọ̀ Jèhófà (Sm 127:3; w21.08 5 ¶9)

Ẹ tọ́ ọmọ kọ̀ọ̀kan bó ṣe yẹ, ẹ má sì fi wọ́n wéra (Sm 127:4; w19.12 27 ¶20)

Jèhófà máa ń mọyì àwọn òbí tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 128:3—Kí nìdí tí onísáàmù ṣe fi àwọn ọmọ wé àwọn ẹ̀ka tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ lára igi ólífì? (it-1 543)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ẹni náà sọ ohun tó gbà gbọ́, àmọ́ kò bá ohun tí Bíbélì sọ mu. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 16 kókó 4-5. Sọ ètò tó o ṣe kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ nìṣó nígbà tí o ò bá sí nílé. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 13

7. Ẹ̀yin Òbí—Ṣé Ẹ̀ Ń Fi Ohun Tó Dáa Jù Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín?

(15 min.) Ìjíròrò.

Ètò Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn òbí lè lò láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà. Àmọ́, àpẹẹrẹ rere táwọn òbí bá fi lélẹ̀ ni ọ̀nà tó dáa jù tí wọ́n lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn.—Di 6:5-9.

Jésù náà fi àpẹẹrẹ tiẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀.

Ka Jòhánù 13:13-15. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó o fi gbà pé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ ni ọ̀nà tó dáa jù láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀?

Ẹ̀yin òbí, ohun tẹ́ ẹ bá ń ṣe máa wọ àwọn ọmọ yín lọ́kàn ju ọ̀rọ̀ ẹnu yín lọ. Tí ìwà yín bá bá ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ àwọn ọmọ yín mu, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n máa gbọ́ràn sí yín lẹ́nu.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ A Fi Àpẹẹrẹ Tó Dáa Lélẹ̀ Fáwọn Ọmọ Wa. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Garcia kọ́ àwọn ọmọ wọn?

  • Kí lo rí kọ́ nínú fídíò yìí tó jẹ́ kó o rí i pé ó yẹ kó o túbọ̀ máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 20 ¶13-20

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 73 àti Àdúrà