Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

ILÉ ÌṢỌ́

Béèrè ìbéèrè: Tó bá jẹ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, ṣé ó máa ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti pa á run?

Ka Bíbélì: Ais 40:8

Fi ìwé lọni: Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ ìtàn tó wọni lọ́kàn nípa bí Ọlọ́run ṣe pa Bíbélì mọ́.

ILÉ ÌṢỌ́ (ẹ̀yìn ìwé)

Béèrè ìbéèrè: Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ mọ èrò yín lórí ìbéèrè yìí. [Ka ìbéèrè àkọ́kọ́ lójú ìwé 16.] Àwọn kan gbà pé àwọn èèyàn ló dá ẹ̀sìn sílẹ̀. Àwọn míì sì gbà pé Ọlọ́run máa ń lo ẹ̀sìn láti fa àwa èèyàn sún mọ́ ara rẹ̀. Kí lèrò yín nípa rẹ̀?

Ka Bíbélì: Jak 1:27

Fi ìwé lọni: Àpilẹ̀kọ yìí sọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. Màá fẹ́ pa dà wá ká lè jíròrò àwọn kókó díẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí.

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Béèrè ìbéèrè: Ọ̀pọ̀ èèyàn ò ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì sí, wọ́n rò pé ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń ka ìwé ìròyìn. Èwo nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí lẹ mọ̀ tó ti nímùúṣẹ?

Ka Bíbélì: 2Ti 3:1-5

Fi ìwé lọni: Ìwé yìí sọ bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ṣe jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. [Ẹ jíròrò ẹ̀kọ́ 1, ìbéèrè 2.]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.