July 11 sí 17
SÁÀMÙ 69-73
Orin 92 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Èèyàn Jèhófà Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́”: (10 min.)
Sm 69:9—Ó yẹ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé lóòótọ́ la jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́ (w10 12/15 ojú ìwé 7 sí 11 ìpínrọ̀ 2 sí 17)
Sm 71:17, 18—Àwọn àgbàlagbà lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ onítara (w14 1/15 ojú ìwé 23 sí 25 ìpínrọ̀ 4 sí 10)
Sm 72:3, 12, 14, 16-19—Ìtara ló ń jẹ́ ká sọ fún àwọn èèyàn nípa nǹkan tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé (w15 10/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3; w10 8/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 19 àti 20)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 69:4, 21—Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ tó ṣẹ sí Mèsáyà lára? (w11 8/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 17; w11 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 15)
Sm 73:24—Báwo ni Jèhófà ṣe ń dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá tàbí mú kí wọ́n wọnú ògo? (w13 2/15 ojú ìwé 25 àti 26 ìpínrọ̀ 3 àti 4)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 73:1-28
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Àwòrán iwájú ìwé ìròyìn wp16.4—Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Àwòrán iwájú ìwé ìròyìn wp16.4
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 5 ìpínrọ̀ 3 àti 4
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ṣé O Lè Gbìyànjú Rẹ̀ Wò fún Ọdún Kan?”: (15 min.) Ní ṣókí, ẹ jíròrò àpilẹ̀kọ náà àti “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé.” Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Mo Yan Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tó Máa Wà Pẹ́ Títí. Kí ẹ sì jíròrò rẹ̀. Ó wà lórí Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW (Lọ sí WO FÍDÍÒ LÓRÍṢIRÍṢI > ÀWỌN Ọ̀DỌ́.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 19 ìpínrọ̀ 17 sí 31, àpótí tó wà lójú ìwé 170 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 171
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 123 àti Àdúrà