MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Lè Gbìyànjú Rẹ̀ Wò fún Ọdún Kan?
Gbìyànjú kí ni? Aṣáájú-ọ̀nà déédéé! Tó o bá gbìyànjú ẹ̀ wò, wàá rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún!—Owe 10:22.
TÓ O BÁ Ń ṢIṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ . . .
-
wàá sunwọ̀n sí i gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, wàá sì túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù
-
wàá túbọ̀ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Bó o bá ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fún àwọn èèyàn ni wàá ṣe túbọ̀ máa rántí àwọn àgbàyanu ànímọ́ rẹ̀
-
wàá ní ìfọ̀kànbalẹ̀ téèyàn máa ń ní tó bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ àti ayọ̀ tó máa ń wá láti inú ríran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.—Mt 6:33; Iṣe 20:35
-
wàá lè lọ sí ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa ń bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe, àkànṣe ìpàdé nígbà àpéjọ àyíká àti Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà
-
wàá láǹfààní púpọ̀ sí i láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá sì máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀
-
wàá máa lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará, wàá sì gbádùn pàṣípààrọ̀ ìṣírí.—Ro 1:11, 12