Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kí Ohun Díẹ̀ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn Kó O Lè Túbọ̀ Máa Yin Ọlọ́run

Jẹ́ Kí Ohun Díẹ̀ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn Kó O Lè Túbọ̀ Máa Yin Ọlọ́run

Lóde òní, ó rọrùn fún wa láti fi ayé nira wa lára tá a bá ń kó ọ̀pọ̀ nǹkan jọ. Ọ̀pọ̀ àkókò àti okun ló máa ń gbà láti lọ ra nǹkan, ká bójú tó o, ká sì tún máa tọ́jú rẹ̀. Jésù jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn torí kò fẹ́ kí àwọn nǹkan tara dí i lọ́wọ́ débi tí kò fi ní lè gbájú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.—Mt 8:20.

Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí àwọn nǹkan tara díẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn kó o lè túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ǹjẹ́ ẹ lè ṣe àwọn àyípadà kan nínú ìdílé yín bóyá ẹnì kan á lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? Tó o bá sì ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ṣé àwọn nǹkan tara ò tíì máa jẹ́ kó ṣòro fún ẹ láti máa ba iṣẹ́ ìsìn rẹ lọ? Tí o kò bá jẹ́ kí àwọn nǹkan tara dí ẹ lọ́wọ́, wàá máa láyọ̀, wàá sì ní ìtẹ́lọ́rùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—1Ti 6:7-9.

Kọ àwọn ọ̀nà tí o lè gbà mú kí ìgbé ayé rẹ túbọ̀ rọrùn.