Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

July 16-​22

Lúùkù 10-11

July 16-​22
  • Orin 100 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • Àpèjúwe Ará Samáríà”: (10 min.)

    • Lk 10:​29-32​—Àlùfáà kan àti ọmọ Léfì kan kọ̀ láti ṣèrànwọ́ fún Júù bíi tiwọn táwọn olè dá lọ́nà [Jẹ́ kí àwọn ará wo “Ọ̀nà Tó Lọ Láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò” àwòrán àti fídíò lórí Lk 10:30, nwtsty] (w02 9/1 16-17 ¶14-15)

    • Lk 10:33-35​—Ará Samáríà kan fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí ẹni táwọn olè dá lọ́nà (“ará Samáríà kan,” “ó sì di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti wáìnì sórí wọn,” “ilé èrò” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 10:33, 34, nwtsty)

    • Lk 10:36, 37​—A gbọ́dọ̀ fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn, kì í ṣe kìkì àwọn tá a jọ wà nípò kan náà, ọmọ ìlú kan náà tàbí tá a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà (w98 7/1 31 ¶2)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Lk 10:18​—Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn àádọ́rin [70] ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run”? (“Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run”  àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 10:18, nwtsty; w08 3/15 31-32 ¶11)

    • Lk 11:5-9​—Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nípa àdúrà nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin tó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè ohun tó fẹ́? (“Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta,” “Yé dà mí láàmú,” “ìtẹpẹlẹ rẹ̀ aláìṣojo” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 11:5-9, nwtsty;)

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lk 10:​1-16

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni náà sọ ohun táwọn kan sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù.

  • Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé òun ń jẹun lọ́wọ́.

  • Ìpadàbẹ̀wò Kejì​—Fídíò: (5 min) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI