Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 12-13

“Ẹ Níye Lórí Ju Ọ̀pọ̀ Ológoṣẹ́”

“Ẹ Níye Lórí Ju Ọ̀pọ̀ Ológoṣẹ́”

12:6, 7

Kí ni Jésù sọ kó tó wá sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Lúùkù 12:​6, 7? Ní ẹsẹ 4, a kà níbẹ̀ pé Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má bẹ̀rù àwọn tó ṣeé ṣe kó ta kò wọ́n tàbí àwọn tó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó pa wọ́n. Ńṣe ni Jésù ń múra àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ fún àtakò tí wọ́n máa dojú kọ. Ó sì mú kó dá wọn lójú pé Jèhófà mọyì ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ àti pé kò ní jẹ́ kí jàǹbá ayérayé ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ará wa tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ń jẹ wá lọ́kàn bíi ti Jèhófà?

Ibo la ti lè rí ìsọfúnni tó dé kẹ́yìn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn?

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mélòó ló wà lẹ́wọ̀n?