MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
Téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá, á rọrùn fún un láti ṣègbọràn sí i. (Owe 3:1) Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé ohun tá à ń kọ́ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má kàn ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ fún un, ṣe ni kó o jẹ́ kó rí bí ohun tó ń kọ́ ṣe kàn án àti bó ṣe lè mú kí àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i. Jẹ́ kó mọyì àwọn ìlànà Jèhófà, kó sì mọ ìdí tó fi fún wa láwọn ìlànà yẹn, ìyẹn á jẹ́ kó gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, pé ìre wa ló ń wà àti pé Ọlọ́run òdodo ni. Máa fọgbọ́n béèrè ìbéèrè tá jẹ́ kó ronú jinlẹ̀, kó sì sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú nípa àǹfààní tá rí tó bá jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa. Inú tìẹ náà máa dùn, tó o bá rí i pé akẹ́kọ̀ọ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ—JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ WỌNI LỌ́KÀN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí nìdí tí Neeta fi béèrè lọ́wọ́ Jade pé: “Ṣé ẹ tún pa dà ronú lórí àwọn nǹkan tá a sọ lọ́jọ́ Monday?”
-
Báwo ni Neeta ṣe jẹ́ kí Jade rí i pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà fún wa láwọn ìlànà ẹ̀?
-
Kí ni Neeta sọ tó jẹ́ kí Jade rí bó ṣe lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?