MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kò Nira Jù Láti Jẹ́ Onígboyà
Ìgboyà túmọ̀ sí pé kéèyàn láyà, kó jẹ́ ẹni tí kì í ṣojo, kó sì jẹ́ akíkanjú. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ẹni yẹn ò ní bẹ̀rù rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe ohun tó tọ́ tẹ́rù bá tiẹ̀ ń bà á. A lè nígboyà tá a bá gbára lé Jèhófà, torí pé òun nìkan ló lè jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà tòótọ́. (Sm 28:7) Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè fi hàn pé wọ́n jẹ́ onígboyà?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ NÍGBOYÀ, KÌ Í ṢE ÀWỌN OJO! KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Àwọn ìṣòro wo làwọn ọ̀dọ́ máa ń kojú tó gba pé kí wọ́n nígboyà?
-
Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tá a lè tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ nígboyà?
-
Àǹfààní wo làwa àtàwọn tó ń wò wa máa rí tá a bá jẹ́ onígboyà?