MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ẹ Má Ṣàníyàn Láé”
Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà máa ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ṣèrànwọ́ fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ aláìní lónìí?
-
Ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní èrò tó tọ́ nípa owó.—Lk 12:15; 1Ti 6:6-8
-
Ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè níyì lójú ara wa.—Job 34:19
-
Ó kọ́ wa pé ó yẹ ká jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ká sì yẹra fún ìwà burúkú.—Owe 14:23; 20:1; 2Kọ 7:1
-
Ó jẹ́ ká ní àwọn ará tó nífẹ̀ẹ́ wa kárí ayé.—Jo 13:35; 1Jo 3:17, 18
-
Ó jẹ́ ká nírètí.—Sm 9:18; Ais 65:21-23
Kò yẹ ká máa ṣàníyàn, tó bá tiẹ̀ dà bíi pé ìṣòro wa pọ̀ lápọ̀jù. (Ais 30:15) Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò tá a bá ṣáà ti fi Ìjọba ẹ̀ sípò àkọ́kọ́ láyé wa.—Mt 6:31-33.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌFẸ́ RẸ YẸ̀ LÁÉ . . . TÓ O BÁ TIẸ̀ JẸ́ TÁLÁKÀ—CONGO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo làwọn ará tó ń gbé nítòsí ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó máa ń rìnrìn àjò wá síbi àpéjọ náà?
-
Báwo ni fídíò yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìní?
-
Tá a bá tiẹ̀ jẹ́ tálákà, báwo la ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn aláìní bíi ti Jèhófà?