ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Bí Jèhófà Ṣe Fẹ́ Ká Máa Sin Òun
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara wọn sìn ín (Di 11:13; it-2 1007 ¶4)
Gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ìsìn èké ni wọ́n gbọ́dọ̀ pa run pátápátá (Di 12:2, 3)
Ibi tí Jèhófà bá yàn ni gbogbo wọn ti gbọ́dọ̀ jọ́sìn (Di 12:11-14; it-1 84 ¶3)
Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn òun máa sin òun tọkàntọkàn, kí wọ́n sá fún ìsìn èké, kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan.