MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI | OHUN TÓ O LÈ FI ṢE ÀFOJÚSÙN NÍ ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN TÓ Ń BỌ̀
Sapá Kó O Lè Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere
Kò dìgbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ geerege nígbèésí ayé rẹ kó o tó lè fi Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere (SKE) ṣe àfojúsùn rẹ. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kó o sì múra tán láti lọ sìn níbikíbi tí ètò Ọlọ́run bá rán ẹ lọ.—Ais 6:8.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ MÚ KÓ O ṢE PÚPỌ̀ SÍ I—SAPÁ KÓ O LÈ LỌ SÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN AJÍHÌNRERE, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ló mú kí Gabriel máa ṣiyèméjì lórí bóyá kóun lọ sílé ẹ̀kọ́ náà tàbí kóun má lọ, báwo sì ni Fílípì 4:13 ṣe ràn án lọ́wọ́?