ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Wọ́n Fi Gbogbo Ọkàn sí Iṣẹ́ Ilé Náà
Àwọn ohun èlò ìkọ́lé tó dáa jù ni Sólómọ́nì fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà (1Ọb 5:6, 17; w11 2/1 15)
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà (1Ọb 5:13-16; it-1 424; it-2 1077 ¶1)
Ọdún méje ni Sólómọ́nì àtàwọn èèyàn náà fi ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n tó parí tẹ́ńpìlì náà (1Ọb 6:38; wo àwòrán iwájú ìwé)
Sólómọ́nì àtàwọn èèyàn náà kọ́ tẹ́ńpìlì tó rẹwà fún Jèhófà torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì fi gbogbo ọkàn sí iṣẹ́ náà. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé, bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ò fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà, wọn ò sì bójú tó tẹ́ńpìlì náà. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, àwọn ọ̀tá pa tẹ́ńpìlì náà run.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Kí ni mò ń ṣe kí ìtara tí mo ní fún ìjọsìn Ọlọ́run má bàa jó rẹ̀yìn?’